6. Orilẹ-ède si kọlù orilẹ-ède, ati ilu si ilu: nitori ti Ọlọrun fi oniruru ipọnju bà wọn ninu jẹ.
7. Ṣugbọn ẹnyin mu ara le, ki ẹ má si dẹ ọwọ nyin: nitori iṣẹ nyin yio ni ère.
8. Nigbati Asa gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, ati asọtẹlẹ Odedi woli, o mu ara le, o si mu awọn ohun irira kuro lati inu gbo-gbo ilẹ Juda ati Benjamini, ati lati inu ilu ti o ti gbà lati oke Efraimu, o si tun pẹpẹ Oluwa ṣe, ti o wà niwaju iloro Oluwa.
9. O si kó gbogbo Juda ati Benjamini jọ, ati awọn alejo ti o pẹlu wọn lati inu Efraimu ati Manasse, ati lati inu Simeoni wá: nitori ti nwọn ya li ọ̀pọlọpọ sọdọ rẹ̀ lati inu Israeli wá, nigbati nwọn ri pe, Oluwa Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀.