2. Kro 14:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Bẹ̃ni Abijah sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu Dafidi: Asa ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. Li ọjọ rẹ̀, ilẹ na wà li alafia li ọdun mẹwa.

2. Asa si ṣe eyi ti o dara, ti o si tọ́ li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀.

3. Nitori ti o mu pẹpẹ awọn ajeji oriṣa kuro, ati ibi giga wọnni, o si wó awọn ere palẹ, o si bẹ ere-oriṣa wọn lulẹ:

4. O si paṣẹ fun Juda lati ma wá Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, ati lati ma pa aṣẹ ati ofin rẹ̀ mọ́.

5. O si mu ibi giga wọnni ati ọwọ̀n-õrun wọnni kuro lati inu gbogbo ilu Juda: ijọba na si wà li alafia niwaju rẹ̀.

6. O si kọ́ ilu olodi wọnni ni Juda, nitoriti ilẹ na ni isimi, on kò si ni ogun li ọdun wọnni; nitori Oluwa ti fun wọn ni isimi.

2. Kro 14