2. Kro 12:6-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nigbana li awọn ijoye Israeli ati ọba rẹ̀ ara wọn silẹ; nwọn si wipe: Oluwa li olododo!

7. Nigbati Oluwa ri pe nwọn rẹ̀ ara wọn silẹ, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Ṣemaiah wá, wipe, Nwọn ti rẹ̀ ara wọn silẹ; nitorina emi kì o run wọn, ṣugbọn emi o fun wọn ni igbala diẹ: a kì yio dà ibinu mi sori Jerusalemu nipa ọwọ Ṣiṣaki.

8. Ṣugbọn nwọn o ma ṣe iranṣẹ rẹ̀: ki nwọn ki o le mọ̀ ìsin mi, ati ìsin ijọba ilẹ wọnni.

9. Bẹ̃ni Ṣiṣaki, ọba Egipti, goke wá si Jerusalemu, o si kó iṣura ile Oluwa lọ, ati iṣura ile ọba; o kó gbogbo rẹ̀: o kó awọn asà wura lọ pẹlu ti Solomoni ti ṣe.

10. Rehoboamu ọba si ṣe asà idẹ ni ipò wọn, o si fi wọn le ọwọ olori ẹṣọ ti ntọju ọ̀na ile ọba.

11. O si ṣe, nigbakugba ti ọba ba si wọ̀ ile Oluwa lọ, awọn ẹṣọ a de, nwọn a si kó wọn wá, nwọn a si kó wọn pada sinu iyara ẹṣọ.

12. Nigbati o si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, ibinu Oluwa yipada kuro lọdọ rẹ̀, ti kò fi run u patapata: ni Juda pẹlu, ohun rere si mbẹ.

2. Kro 12