5. Rehoboamu si ngbe Jerusalemu, o si kọ́ ilu olodi ni Juda.
6. O kọ́ Betlehemu pẹlu, ati Etamu, ati Tekoa,
7. Ati Bet-Suri, ati Soko, ati Adullamu,
8. Ati Gati, ati Mareṣa, ati Sifu,
9. Ati Adoraimu, ati Lakiṣi, ati Aseki,
10. Ati Sora, ati Aijaloni, ati Hebroni, ti o wà ni Juda ati ni Benjamini, awọn ilu olodi.
11. O si mu awọn ilu olodi lagbara, o si fi awọn balogun sinu wọn ati akojọ onjẹ, ati ororo ati ọti-waini.
12. Ati ni olukuluku ilu li o fi asà ati ọ̀kọ si, o si mu wọn lagbara gidigidi, o si ni Juda ati Benjamini labẹ rẹ̀.
13. Ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ti o wà ni gbogbo Israeli, tọ̀ ọ lọ lati gbogbo ibugbe wọn wá.