4. Bayi li Oluwa wi, ẹnyin kò gbọdọ gòke lọ, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ba awọn arakunrin nyin jà: ki olukuluku pada si ile rẹ̀: nitori ọ̀ran yi lati ọdọ mi wá ni. Nwọn si gbà ọ̀rọ Oluwa gbọ́, nwọn si yipada kuro lati lọ iba Jeroboamu.
5. Rehoboamu si ngbe Jerusalemu, o si kọ́ ilu olodi ni Juda.
6. O kọ́ Betlehemu pẹlu, ati Etamu, ati Tekoa,
7. Ati Bet-Suri, ati Soko, ati Adullamu,
8. Ati Gati, ati Mareṣa, ati Sifu,
9. Ati Adoraimu, ati Lakiṣi, ati Aseki,
10. Ati Sora, ati Aijaloni, ati Hebroni, ti o wà ni Juda ati ni Benjamini, awọn ilu olodi.
11. O si mu awọn ilu olodi lagbara, o si fi awọn balogun sinu wọn ati akojọ onjẹ, ati ororo ati ọti-waini.