2. Kro 1:4-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Apoti-ẹri Ọlọrun ni Dafidi ti gbé lati Kirjat-jearimu wá si ibi ti Dafidi ti pese silẹ fun u, nitoriti o ti pa agọ kan silẹ fun u ni Jerusalemu.

5. Ṣugbọn pẹpẹ idẹ ti Besaleeli, ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ṣe, wà nibẹ niwaju agọ Oluwa: Solomoni ati ijọ enia si wá a ri.

6. Solomoni si lọ si ibi pẹpẹ idẹ niwaju Oluwa, ti o ti wà nibi agọ ajọ, o si rú ẹgbẹrun ẹbọ-sisun lori rẹ̀.

7. Li oru na li Oluwa fi ara hàn Solomoni, o si wi fun u pe, Bère ohun ti emi o fi fun ọ.

8. Solomoni si wi fun Ọlọrun pe, Iwọ ti fi ãnu nla hàn baba mi, o si ti mu mi jọba ni ipò rẹ̀.

9. Nisisiyi Oluwa Ọlọrun, jẹ ki a mu ọ̀rọ rẹ fun Dafidi baba mi ṣẹ: nitoriti iwọ ti fi mi jọba lori awọn enia ti o pọ̀ bi erupẹ ilẹ.

10. Fun mi li ọgbọ́n ati ìmọ nisisiyi, ki emi le ma wọ ile, ki nsi ma jade niwaju enia yi: nitoripe, tani le ṣe idajọ enia rẹ yi ti o pọ̀ to yi.

2. Kro 1