15. Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹniti o kó pọ̀ju, kò ni nkan le; ẹniti o si kó kere ju, kò ṣe alainito.
16. Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun, ẹniti o fi itara aniyan kanna yi si ọkàn Titu fun nyin.
17. Nitori on gbà ọ̀rọ iyanju nitõtọ; ṣugbọn bi o ti ni itara pipọ, on tikararẹ̀ tọ̀ nyin wá fun ara rẹ̀.
18. Awa ti rán arakunrin na pẹlu rẹ̀, iyìn ẹniti o wà ninu ihinrere yiká gbogbo ijọ.
19. Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn ẹniti a ti yàn pẹlu lati ọdọ ijọ wá lati mã bá wa rìn kiri ninu ọran ore-ọfẹ yi, ti awa nṣe iranṣẹ rẹ̀ fun ogo Oluwa, ati imura-tẹlẹ wa.