2. Kor 3:5-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Kì iṣe pe awa to fun ara wa lati ṣirò ohunkohun bi ẹnipe lati ọdọ awa tikarawa; ṣugbọn lati ọdọ Ọlọrun ni tito wa;

6. Ẹniti o mu wa tó bi iranṣẹ majẹmu titun; kì iṣe ti iwe, bikoṣe ti ẹmí: nitori iwe a mã pani, ṣugbọn ẹmí a mã sọni di ãye.

7. Ṣugbọn bi iṣẹ-iranṣẹ ti ikú, ti a ti kọ ti a si ti gbẹ́ si ara okuta, ba jẹ ologo, tobẹ̃ ti awọn ọmọ Israeli kò le tẹjumọ ati wò oju Mose, nitori ogo oju rẹ̀ (ogo nkọja lọ),

8. Yio ha ti ri ti iṣẹ-iranṣẹ ti ẹmí kì yio kuku jẹ ogo jù?

9. Nitoripe bi iṣẹ-iranṣẹ idalẹbi ba jẹ ologo, melomelo ni iṣẹ-iranṣẹ ododo yio rekọja li ogo.

2. Kor 3