2. Kor 3:16-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Ṣugbọn nigbati on o ba yipada si Oluwa, a o mu iboju na kuro.

17. Njẹ Oluwa li Ẹmí na: nibiti Ẹmí Oluwa ba si wà, nibẹ̀ li omnira gbé wà.

18. Ṣugbọn gbogbo wa nwò ogo Oluwa laisi iboju bi ẹnipe ninu awojiji, a si npawada si aworan kanna lati ogo de ogo, ani bi lati ọdọ Oluwa ti iṣe Ẹmí.

2. Kor 3