1. AWA ha tún bẹ̀rẹ lati mã yìn ara wa bi? tabi awa ha nfẹ iwe iyìn sọdọ nyin, tabi lati ọdọ nyin bi awọn ẹlomiran?
2. Ẹnyin ni iwe wa, ti a ti kọ si wa li ọkàn, ti gbogbo enia ti mọ̀, ti nwọn sì ti kà:
3. Bi a ti fi nyin hàn pe, iwe Kristi ni nyin, ti a nṣe iranṣẹ fun, kì iṣe eyiti a fi tadawa kọ, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun alãye; kì iṣe ninu tabili okuta, bikoṣe ninu tabili ọkàn ẹran.
4. Irú igbẹkẹle yi li awa si ni nipa Kristi sọdọ Ọlọrun: