15. Nitorina kì iṣe ohun nla bi awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu ba pa ara wọn dà bi awọn iranṣẹ ododo; igbẹhin awọn ẹniti yio ri gẹgẹ bi iṣẹ wọn.
16. Mo si tún wipe, Ki ẹnikẹni ki o máṣe rò pe aṣiwère ni mi; ṣugbọn bi bẹ̃ ba ni, ẹ gbà mi bi aṣiwere, ki emi ki o le gbé ara mi ga diẹ.
17. Ohun ti emi nsọ, emi kò sọ ọ nipa ti Oluwa, ṣugbọn bi aṣiwèrè ninu igbẹkẹle iṣogo yi.
18. Ọpọlọpọ li o sa nṣogo nipa ti ara, emi ó ṣogo pẹlu.
19. Nitori ẹnyin fi inu didùn gbà awọn aṣiwère, nigbati ẹnyin tikaranyin jẹ ọlọ́gbọn.
20. Nitori ẹnyin farada a bi ẹnikan ba sọ nyin di ondè, bi ẹnikan ba jẹ nyin run, bi ẹnikan ba gbà lọwọ nyin, bi ẹnikan ba gbé ara rẹ̀ ga, bi ẹnikan ba gbá nyin loju.
21. Emi nwi lọna ẹ̀gan, bi ẹnipe awa jẹ alailera. Ṣugbọn ninu ohunkohun ti ẹnikan ni igboiya (emi nsọrọ were), emi ni igboiya pẹlu.
22. Heberu ni nwọn bi? bẹ̃li emi. Israeli ni nwọn bi? bẹ̃li emi. Irú ọmọ Abrahamu ni nwọn bi? bẹ̃li emi.
23. Iranṣẹ Kristi ni nwọn bi? (emi nsọ bi aṣiwère) mo ta wọn yọ; niti lãlã lọpọlọpọ, niti paṣan mo rekọja, niti tubu nigbakugba, niti ikú nigbapupọ.
24. Nigba marun ni mo gbà paṣan ogoji dín kan lọwọ awọn Ju.
25. Nigba mẹta li a fi ọgọ lù mi, ẹkanṣoṣo li a sọ mi li okuta, ẹ̃mẹta li ọkọ̀ rì mi, ọsán kan ati oru kan ni mo wà ninu ibú.
26. Ni ìrin àjò nigbakugba, ninu ewu omi, ninu ewu awọn ọlọṣa, ninu ewu awọn ara ilu mi, ninu ewu awọn keferi, ninu ewu ni ilu, ninu ewu li aginjù, ninu ewu loju okun, ninu ewu larin awọn eke arakunrin;
27. Ninu lãlã ati irora, ninu iṣọra nigbakugba, ninu ebi ati orùngbẹ, ninu àwẹ nigbakugba, ninu otutù ati ìhoho.
28. Pẹlu nkan wọnni ti o wà lode, eyi ti nwọjọ tì mi li ojojumọ́, emi ko yé ṣe aniyan gbogbo ijọ.