2. Kor 1:3-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Olubukún li Ọlọrun, ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Baba iyọ́nu, ati Ọlọrun itunu gbogbo;

4. Ẹniti ntù wa ninu ni gbogbo wahalà wa, nipa itunu na ti a fi ntù awa tikarawa ninu lati ọdọ Ọlọrun wá, ki awa ki o le mã tù awọn ti o wà ninu wahala-ki-wahala ninu.

5. Nitoripe bi ìya Kristi ti di pipọ ninu wa, gẹgẹ bẹ̃ni itunu wa di pipọ pẹlu nipa Kristi.

2. Kor 1