10. Bi ẹnikẹni bá tọ̀ nyin wá, ti kò si mu ẹkọ́ yi wá, ẹ máṣe gbà a si ile, ki ẹ má si ṣe kí i.
11. Nitori ẹniti o ba ki i, o ni ọwọ́ ninu iṣẹ buburu rẹ̀.
12. Bi mo ti ni ohun pupọ̀ lati kọwe si nyin, emi kò fẹ lo tákàdá ati tàdãwa. Ṣugbọn emi ni ireti lati tọ nyin wá ati lati ba nyin sọrọ lojukoju, ki ayọ̀ nyin ki o le kún.
13. Awọn ọmọ arabinrin rẹ ayanfẹ ki ọ. Amin.