9. Nigbana ni nwọn wi fun ara wọn pe, Awa kò ṣe rere: oni yi, ọjọ ihinrere ni, awa si dakẹ: bi awa ba duro titi di afẹmọjumọ, iyà yio jẹ wa: njẹ nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a si lọ isọ fun awọn ara ile ọba.
10. Bẹ̃ni nwọn wá, nwọn si ke si awọn onibodè ilu; nwọn si wi fun wọn pe, Awa de bùdo awọn ara Siria, si kiyesi i, kò si ọkunrin kan nibẹ, bẹ̃ni kò si ohùn enia kan, bikòṣe ẹṣin ti a so, ati kẹtẹkẹtẹ ti a so, ati agọ bi nwọn ti wà.
11. Ẹnikan si pè awọn onibodè; nwọn si sọ ninu ile ọba.
12. Ọba si dide li oru, o si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Emi o fi hàn nyin nisisiyi eyiti awọn ara Siria ti ṣe si wa. Nwọn mọ̀ pe, ebi npa wa; nitorina nwọn jade lọ ni bùdo lati fi ara wọn pamọ́ ni igbẹ wipe, Nigbati nwọn ba jade ni ilu, awa o mu wọn lãyè, awa o si wọ̀ inu ilu lọ.