24. O si ṣe lẹhìn eyi, ni Benhadadi ọba Siria ko gbogbo ogun rẹ̀ jọ, nwọn si gòke, nwọn si dó tì Samaria.
25. Iyàn nla kan si mu ni Samaria: si kiyesi i, nwọn dó tì i, tobẹ̃ ti a si fi ntà ori kẹtẹkẹtẹ kan ni ọgọrun iwọ̀n fadakà, ati idamẹrin oṣuwọn kabu imi ẹiyẹle, ni iwọ̀n fàdakà marun.
26. O si ṣe ti ọba Israeli nkọja lọ lori odi, obinrin kan sọkún tọ̀ ọ wá wipe, Gbà mi, oluwa mi, ọba!
27. On si wipe, Bi Oluwa kò ba gbà ọ, nibo li emi o gbe ti gbà ọ? Lati inu ilẹ-ipakà, tabi lati inu ibi ifunti?
28. Ọba si wi fun u pe, Ẽṣe ọ? On si dahùn wipe, Obinrin yi wi fun mi pe, Mu ọmọkunrin rẹ wá, ki awa ki o le jẹ ẹ loni, awa o si jẹ ọmọ ti emi li ọla.
29. Bẹ̃ni awa sè ọmọ mi, awa si jẹ ẹ́: emi si wi fun u ni ijọ keji pe, Mu ọmọ rẹ wá ki awa ki o jẹ́ ẹ; on si ti fi ọmọ rẹ̀ pamọ́.
30. O si ṣe, nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ obinrin na, o fà aṣọ rẹ̀ ya; o si kọja lọ lori odi, awọn enia si wò, si kiyesi i, o ni aṣọ-ọfọ̀ labẹ aṣọ rẹ̀ li ara rẹ̀.
31. Nigbana ni o wipe, Ki Ọlọrun ki o ṣe bayi ati jù bẹ̃ lọ si mi, bi ori Eliṣa ọmọ Ṣafati yio duro li ọrùn rẹ̀ li oni.