1. NJẸ Naamani, olori-ogun ọba Siria, jẹ enia nla niwaju oluwa rẹ̀, ati ọlọla, nitori nipa rẹ̀ ni Oluwa ti fi iṣẹgun fun Siria: on si jẹ alagbara akọni ọkunrin ṣugbọn adẹtẹ̀ ni.
2. Awọn ara Siria si ti jade lọ ni ẹgbẹ́-ẹgbẹ́, nwọn si ti mu ọmọbinrin kekere kan ni igbèkun lati ilẹ Israeli wá; on si duro niwaju obinrin Naamani.
3. On si wi fun iya rẹ̀ pe, oluwa mi iba wà niwaju woli ti mbẹ ni Samaria! nitõtọ on iba wò o sàn kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀.
4. On si wọle, o si sọ fun oluwa rẹ̀ pe, Bayi bayi li ọmọdebinrin ti o ti ilẹ Israeli wá wi.
5. Ọba Siria si wipe, Wá na, lọ, emi o si fi iwe ranṣẹ si ọba Israeli. On si jade lọ, o si mu talenti fàdakà mẹwa lọwọ, ati ẹgbãta iwọ̀n wurà, ati ipãrọ aṣọ mẹwa.
6. On si mu iwe na tọ̀ ọba Israeli wá, wipe, Njẹ nisisiyi nigbati iwe yi ba de ọdọ rẹ, kiyesi i, emi rán Naamani iranṣẹ mi si ọ, ki iwọ ki o le wò o sàn kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀.