2. A. Ọba 4:31-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

31. Gehasi si kọja siwaju wọn, o si fi ọpá na le ọmọ na ni iwaju, ṣugbọn kò si ohùn, tabi afiyesi: nitorina o si tun pada lati lọ ipade rẹ̀, o si wi fun u pe, Ọmọ na kò ji.

32. Nigbati Eliṣa si wọ̀ inu ile, kiyesi i, ọmọ na ti kú, a si tẹ́ ẹ sori ibùsun rẹ̀.

33. O si wọ̀ inu ile lọ, o si se ilẹ̀kun mọ awọn mejeji, o si gbadura si Oluwa.

34. On si gòke, o si dubulẹ le ọmọ na, o si fi ẹnu rẹ̀ le ẹnu rẹ̀, ati oju rẹ̀ le oju rẹ̀, ati ọwọ rẹ̀ le ọwọ rẹ̀: on si nà ara rẹ̀ le ọmọ na, ara ọmọ na si di gbigboná.

35. O si pada, o si rìn lọ, rìn bọ̀ ninu ile lẹ̃kan; o si gòke, o si nà ara rẹ̀ le e; ọmọ na si sín nigba meje; ọmọ na si là oju rẹ̀.

36. O si pè Gehasi, o si wipe, Pè ara Ṣunemu yi wá. O si pè e. Nigbati o si wọle tọ̀ ọ wá, o ni, Gbé ọmọ rẹ.

37. Nigbana li o wọ̀ inu ile, o si wolẹ li ẹba ẹṣẹ̀ rẹ̀, o si dojubolẹ, o si gbé ọmọ rẹ̀, o si jade lọ.

38. Eliṣa si tun pada wá si Gilgali, iyàn si mu ni ilẹ na; awọn ọmọ awọn woli joko niwaju rẹ̀: on si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Gbe ìkoko nla ka iná, ki ẹ si pa ipẹ̀tẹ fun awọn ọmọ awọn woli.

2. A. Ọba 4