2. A. Ọba 25:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li ọdun kẹsan ijọba rẹ̀, li oṣù kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣù, ni Nebukadnessari ọba Babeli de, on, ati gbogbo ogun rẹ̀, si Jerusalemu, o si dotì i; nwọn si mọdi tì i yika kiri.

2. A si dotì ilu na titi di ọdun ikọkanla Sedekiah.

3. Ati li ọjọ kẹsan oṣù kẹrin, iyàn mu gidigidi ni ilu, kò si si onjẹ fun awọn enia ilẹ na.

2. A. Ọba 25