35. Jehoiakimu si fi fadakà ati wura na fun Farao; ṣugbọn o bu owo-odè fun ilẹ na lati san owo na gẹgẹ bi ofin Farao: o fi agbara gbà fadakà ati wurà na lọwọ awọn enia ilẹ na, lọwọ olukuluku gẹgẹ bi owo ti a bù fun u, lati fi fun Farao-Neko.
36. Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni Jehoiakimu nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Sebuda, ọmọbinrin Bedaiah ti Ruma.
37. On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn baba rẹ̀ ti ṣe.