3. O si ṣe li ọdun kejidilogun Josiah ọba li ọba rán Ṣafani ọmọ Asaliah ọmọ Mesullamu, akọwe, si ile Oluwa, wipe,
4. Gòke tọ̀ Hilkiah olori alufa lọ, ki o le ṣirò iye fadakà ti a mu wá sinu ile Oluwa, ti awọn olùtọju iloro ti kojọ lọwọ awọn enia:
5. Ẹ si jẹ ki wọn ki o fi le awọn olùṣe iṣẹ na lọwọ, ti nṣe alabojuto ile Oluwa: ki ẹ si jẹ ki wọn ki o fi fun awọn olùṣe iṣẹ na ti mbẹ ninu ile Oluwa, lati tun ibi ẹya ile na ṣe.
6. Fun awọn gbẹnagbẹna, ati fun awọn akọle, ati awọn ọ̀mọle, lati rà ìti-igi ati okuta gbígbẹ lati tún ile na ṣe.
7. Ṣugbọn a kò ba wọn ṣe iṣirò owo ti a fi le wọn lọwọ, nitoriti nwọn ṣe otitọ.
8. Hilkiah olori alufa si sọ fun Ṣafani akọwe pe, Emi ri iwe ofin ni ile Oluwa. Hilkiah si fi iwe na fun Ṣafani, on si kà a.