2. A. Ọba 21:20-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, bi baba rẹ̀ Manasse ti ṣe.

21. O si rìn li ọ̀na gbogbo ti baba rẹ̀ rìn, o si sìn awọn ere ti baba rẹ̀ sìn, o si bọ wọn:

22. On si kọ̀ OLUWA Ọlọrun awọn baba rẹ̀ silẹ, kò si rìn li ọ̀na Oluwa.

23. Awọn iranṣẹ Amoni si dìtẹ si i, nwọn si pa ọba ni ile rẹ̀.

24. Awọn enia ilẹ na si pa gbogbo awọn ti o dìtẹ si Amoni ọba: awọn enia ilẹ na si fi Josiah ọmọ rẹ̀ jọba ni ipò rẹ̀.

2. A. Ọba 21