6. Emi o si bù ọdun mẹ̃dogun kún ọjọ rẹ: emi o si gbà ọ ati ilu yi lọwọ ọba Assiria, emi o si dãbò bò ilu yi, nitori ti emi tikara mi, ati nitori ti Dafidi iranṣẹ mi.
7. Isaiah si wipe, Mu odidi ọ̀pọtọ. Nwọn si mu u, nwọn si fi le õwo na, ara rẹ̀ si da.
8. Hesekiah si wi fun Isaiah pe, Kini yio ṣe àmi pe Oluwa yio wò mi sàn, ati pe emi o gòke lọ si ile Oluwa ni ijọ kẹta?
9. Isaiah si wipe, Àmi yi ni iwọ o ni lati ọdọ Oluwa wá, pe, Oluwa yio ṣe nkan yi ti on ti sọ: ki ojiji ki o lọ siwaju ni iṣisẹ̀ mẹwa ni, tabi ki o pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa?
10. Hesekiah si dahùn wipe, Ohun ti o rọrùn ni fun ojiji ki o lọ siwaju ni iṣisẹ̀ mẹwa: bẹ̃kọ, ṣugbọn jẹ ki ojiji ki o pada sẹhin ni iṣisẹ̀ mẹwa.