2. A. Ọba 2:2-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Elijah si wi fun Eliṣa pe, Emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitoriti Oluwa rán mi si Beteli. Eliṣa si wi fun u pe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Bẹ̃ni nwọn sọ̀kalẹ lọ si Beteli.

3. Awọn ọmọ awọn woli ti mbẹ ni Beteli jade tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ pe Oluwa yio mu oluwa rẹ lọ kuro li ori rẹ loni? On si wipe, Bẹ̃ni, emi mọ̀, ẹ pa ẹnu nyin mọ́.

4. Elijah si wi fun u pe, Eliṣa, emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitori ti Oluwa rán mi si Jeriko. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Bẹ̃ni nwọn de Jeriko.

5. Awọn ọmọ awọn woli ti mbẹ ni Jeriko tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ pe Oluwa yio mu oluwa rẹ lọ kuro li ori rẹ loni? On si dahùn wipe, Bẹ̃ni, emi mọ̀, ẹ pa ẹnu nyin mọ́.

6. Elijah si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, joko nihinyi; nitoriti Oluwa rán mi si Jordani. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. Awọn mejeji si jùmọ nlọ.

7. Adọta ọkunrin ninu awọn ọmọ awọn woli si lọ, nwọn si duro lati wò lòkere rére: awọn mejeji si duro li ẹba Jordani.

8. Elijah si mu agbáda rẹ̀, o si lọ́ ọ lù, o si lù omi na, o si pin wọn ni iyà sihin ati sọhun, bẹ̃ni awọn mejeji si kọja ni ilẹ gbigbẹ.

9. O si ṣe, nigbati nwọn kọja tan, ni Elijah wi fun Eliṣa pe, Bère ohun ti emi o ṣe fun ọ, ki a to gbà mi kuro lọwọ rẹ. Eliṣa si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ìlọ́po meji ẹmi rẹ ki o bà le mi.

10. On si wipe, Iwọ bère ohun ti o ṣoro: ṣugbọn, bi iwọ ba ri mi nigbati a ba gbà mi kuro lọdọ rẹ, yio ri bẹ̃ fun ọ; ṣugbọn bi bẹ̃ kọ, kì yio ri bẹ̃.

2. A. Ọba 2