8. Ahasi si mu fadakà ati wura ti a ri ni ile Oluwa, ati ninu iṣura ile ọba, o si rán a li ọrẹ si ọba Assiria.
9. Ọba Assiria si gbọ́ tirẹ̀: nitoriti ọba Assiria gòke wá si Damasku, o si kó o, o si mu u ni igbèkun lọ si Kiri, o si pa Resini.
10. Ahasi ọba si lọ si Damasku lati pade Tiglat-pileseri, ọba Assiria, o si ri pẹpẹ kan ti o wà ni Damasku: Ahasi ọba si rán awòran pẹpẹ na, ati apẹrẹ rẹ̀ si Urijah alufa, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ ọnà rẹ̀.
11. Urijah alufa si ṣe pẹpẹ kan gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ahasi ọba fi ranṣẹ si i lati Damasku wá; bẹ̃ni Urijah alufa ṣe e de atibọ̀ Ahasi ọba lati Damasku wá.
12. Nigbati ọba si ti Damasku de, ọba si ri pẹpẹ na: ọba si sunmọ pẹpẹ na, o si rubọ lori rẹ̀.
13. O si sun ẹbọ ọrẹ-sisun rẹ̀ ati ọrẹ-jijẹ rẹ̀, o si ta ohun-mimu rẹ̀ silẹ, o si wọ́n ẹ̀jẹ ọrẹ-alafia rẹ̀ si ara pẹpẹ na.