4. Kiki ibi giga wọnni ni a kò mu kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni.
5. Oluwa si kọlù ọba na, bẹ̃li o di adẹtẹ̀ titi di ọjọ ikú rẹ̀, o si ngbe ile ihámọ: Jotamu ọmọ ọba si wà lori ile na, o nṣe idajọ awọn enia ilẹ na.
6. Ati iyokù iṣe Asariah, ati ohun gbogbo ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
7. Asariah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀, ni ilu Dafidi: Jotamu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
8. Li ọdun kejidilogoji Asariah ọba Juda ni Sakariah ọmọ Jeroboamu jọba lori Israeli ni Samaria li oṣù mẹfa.
9. O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa, bi awọn baba rẹ̀ ti ṣe: on kò kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀.
10. Ṣallumu ọmọ Jabeṣi si dì rikiṣi si i, o si kọlù u niwaju awọn enia, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀.
11. Ati iyokù iṣe Sakariah, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.
12. Eyi li ọ̀rọ Oluwa ti o ti sọ fun Jehu wipe, Awọn ọmọ rẹ iran kẹrin yio joko lori itẹ Israeli, bẹ̃li o si ri.