29. Li ọjọ Peka ọba Israeli ni Tiglat-pileseri ọba Assiria de, o si kó Ijoni, ati Abel-betmaaka, ati Janoa, ati Kedeṣi, ati Hasori, ati Gileadi, ati Galili, gbogbo ilẹ Naftali, o si kó wọn ni igbèkun lọ si Assiria.
30. Hoṣea ọmọ Ela si dì rikiṣi si Peka ọmọ Remaliah, o si kọlù u, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀, li ogun ọdun Jotamu ọmọ Ussiah.
31. Ati iyokù iṣe Peka, ati gbogbo eyiti o ṣe, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.
32. Li ọdun keji Peka ọmọ Remaliah ọba Israeli, ni Jotamu ọmọ Ussiah ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.
33. Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Jeruṣa, ọmọbinrin Sadoku.
34. O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa: o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ussiah baba rẹ̀ ti ṣe.
35. Ṣugbọn a kò mu ibi giga wọnni kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni. On kọ́ ẹnu-ọ̀na giga ile Oluwa.