2. A. Ọba 15:22-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Menahemu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Pekahiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

23. Ni ãdọta ọdun Asariah ọba Juda, Pekahiah ọmọ Menahemu bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba ọdun meji.

24. O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa: on kò si lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀.

25. Ṣugbọn Peka ọmọ Remaliah, olori-ogun rẹ̀, dì rikiṣi si i, o si kọlù u ni Samaria, li odi ile ọba, pẹlu Argobu, ati Arie, ati ãdọta enia ninu awọn ọmọ Gileadi pẹlu rẹ̀: o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀.

26. Ati iyokù iṣe Pekahiah, ati gbogbo eyiti o ṣe, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

27. Li ọdun kejilelãdọta Asariah ọba Juda ni Peka ọmọ Remaliah bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria, o si jọba li ogun ọdun.

28. O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa: on kò lọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀.

29. Li ọjọ Peka ọba Israeli ni Tiglat-pileseri ọba Assiria de, o si kó Ijoni, ati Abel-betmaaka, ati Janoa, ati Kedeṣi, ati Hasori, ati Gileadi, ati Galili, gbogbo ilẹ Naftali, o si kó wọn ni igbèkun lọ si Assiria.

30. Hoṣea ọmọ Ela si dì rikiṣi si Peka ọmọ Remaliah, o si kọlù u, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀, li ogun ọdun Jotamu ọmọ Ussiah.

31. Ati iyokù iṣe Peka, ati gbogbo eyiti o ṣe, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

32. Li ọdun keji Peka ọmọ Remaliah ọba Israeli, ni Jotamu ọmọ Ussiah ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.

33. Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Jeruṣa, ọmọbinrin Sadoku.

34. O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa: o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ussiah baba rẹ̀ ti ṣe.

35. Ṣugbọn a kò mu ibi giga wọnni kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni. On kọ́ ẹnu-ọ̀na giga ile Oluwa.

36. Ati iyokù iṣe Jotamu, ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

37. Li ọjọ wọnni Oluwa bẹ̀rẹ si irán Resini ọba Siria, ati Peka ọmọ Remaliah si Juda.

38. Jotamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi baba rẹ̀, Ahasi ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

2. A. Ọba 15