2. A. Ọba 15:1-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọdun kẹtadilọgbọ̀n Jeroboamu ọba Israeli ni Asariah (Ussiah) ọmọ Amasiah ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.

2. Ẹni ọdun mẹrindilogun li on iṣe nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mejilelãdọta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ a ma jẹ Jekoliah ti Jerusalemu.

3. O si ṣe eyiti o tọ loju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ Amasiah ti ṣe;

4. Kiki ibi giga wọnni ni a kò mu kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni.

5. Oluwa si kọlù ọba na, bẹ̃li o di adẹtẹ̀ titi di ọjọ ikú rẹ̀, o si ngbe ile ihámọ: Jotamu ọmọ ọba si wà lori ile na, o nṣe idajọ awọn enia ilẹ na.

6. Ati iyokù iṣe Asariah, ati ohun gbogbo ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

7. Asariah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀, ni ilu Dafidi: Jotamu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

8. Li ọdun kejidilogoji Asariah ọba Juda ni Sakariah ọmọ Jeroboamu jọba lori Israeli ni Samaria li oṣù mẹfa.

9. O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa, bi awọn baba rẹ̀ ti ṣe: on kò kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀.

10. Ṣallumu ọmọ Jabeṣi si dì rikiṣi si i, o si kọlù u niwaju awọn enia, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀.

11. Ati iyokù iṣe Sakariah, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

12. Eyi li ọ̀rọ Oluwa ti o ti sọ fun Jehu wipe, Awọn ọmọ rẹ iran kẹrin yio joko lori itẹ Israeli, bẹ̃li o si ri.

13. Ṣallumu ọmọ Jabeṣi bẹ̀rẹ si ijọba li ọdun kọkandilogoji Ussiah ọba Juda; o si jọba oṣù kan gbáko ni Samaria.

14. Nitoriti Menahemu ọmọ Gadi gòke lati Tirsa lọ, o si wá si Samaria, o si kọlù Ṣallumi ọmọ Jabeṣi ni Samaria, o si pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀.

15. Ati iyokù iṣe Ṣallumu, ati rikiṣi rẹ̀ ti o dì, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

16. Nigbana ni Menahemu kọlù Tifsa, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀, ati ilẹ agbègbe rẹ̀ wọnni lati Tifsa lọ: nitoriti nwọn kò ṣi i silẹ fun u, nitorina li o ṣe kọlù u; ati gbogbo awọn obinrin aboyun inu rẹ̀ li o là ni inu.

2. A. Ọba 15