2. A. Ọba 11:12-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. On si mu ọmọ ọba na jade wá o si fi ade de e lori, o si fun u ni iwe-ẹ̀ri; nwọn si fi i jọba, nwọn si fi ororo yàn a; nwọn si pàtẹwọ wọn, nwọn si wipe, Ki ọba ki o pẹ.

13. Nigbati Ataliah gbọ́ ariwo awọn ẹ̀ṣọ ati ti awọn enia, o tọ̀ awọn enia na wá ninu ile Oluwa.

14. Nigbati o si wò, kiyesi i, ọba duro ni ibuduro na, gẹgẹ bi iṣe wọn, ati awọn balogun, ati awọn afunpè duro lọdọ ọba; gbogbo enia ilẹ na si yọ̀, nwọn si fun ipè: Ataliah si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si kigbe, pe, Ọtẹ̀! Ọtẹ̀!

15. Ṣugbọn Jehoiada alufa paṣẹ fun awọn olori ọ̀rọrún, ati awọn olori ogun, o si wi fun wọn pe, Ẹ mu u jade lati inu ile arin ẹgbẹ ogun: ẹniti o ba si tọ̀ ọ lẹhin ni ki ẹ fi idà pa. Nitoriti alufa na ti wipe, Ki a máṣe pa a ninu ile Oluwa.

16. Nwọn si gbé ọwọ le e; on si gbà ọ̀na ti awọn ẹṣin ngbà wọ̀ ile ọba: nibẹ ni a si pa a.

17. Jehoiada si da majẹmu lãrin Oluwa ati ọba ati awọn enia, pe, ki nwọn ki o mã ṣe enia Oluwa; ati lãrin ọba pẹlu awọn enia.

18. Gbogbo enia ilẹ na si lọ sinu ile Baali, nwọn si wo o lulẹ: awọn pẹpẹ rẹ̀ ati awọn ere rẹ̀ ni nwọn fọ́ tútu patapata, nwọn si pa Mattani alufa Baali niwaju pẹpẹ na. Alufa na si yàn awọn olori si ile Oluwa.

2. A. Ọba 11