2. A. Ọba 11:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI Ataliah iyá Ahasiah si ri pe ọmọ on kú, o dide, o si pa gbogbo iru-ọmọ ọba run.

2. Ṣugbọn Jehoṣeba ọmọbinrin Joramu ọba, arabinrin Ahasiah, mu Joaṣi ọmọ Ahasiah, o si ji i gbé kuro ninu awọn ọmọ ọba ti a pa; nwọn si pa a mọ́ ninu iyẹ̀wu kuro lọdọ Ataliah, on, ati alagbatọ́ rẹ̀, ti a kò si fi pa a.

3. A si pa a mọ́ pẹlu rẹ̀ ni ile Oluwa li ọdun mẹfa. Ataliah si jọba lori ilẹ na.

4. Li ọdun keje Jehoiada si ranṣẹ o si mu awọn olori lori ọ̀rọrún, pẹlu awọn balogun, ati awọn olùṣọ, o si mu wọn wá si ọdọ rẹ̀ sinu ile Oluwa, o si ba wọn da majẹmu, o si mu wọn bura ni ile Oluwa, o si fi ọmọ ọba hàn wọn.

5. O si paṣẹ fun wọn wipe, Eyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe; Idamẹta nyin ti nwọle li ọjọ isimi, yio ṣe olùtọju iṣọ ile ọba;

6. Idamẹta yio si wà li ẹnu ọ̀na Suri; idamẹta yio si wà li ẹnu-ọ̀na lẹhin ẹ̀ṣọ: bẹ̃li ẹnyin o tọju iṣọ́ ile na, lati da abo bò o.

7. Ati idajì gbogbo ẹnyin ti njade lọ li ọjọ isimi, ani awọn ni yio tọju iṣọ ile Oluwa yi ọba ka.

8. Ẹnyin o si pa agbo yi ọba ka, olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀: ẹniti o ba si wọ̀ arin ẹgbẹ́ ogun na, ki a pa a: ki ẹnyin ki o si wà pẹlu ọba bi o ti njade lọ, ati bi o ti mbọ̀wá ile.

9. Awọn olori ọrọrun ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiada alufa pa li aṣẹ: olukuluku wọn si mu awọn ọkunrin tirẹ̀ ti ibá wọle wá li ọjọ isimi, pẹlu awọn ti iba jade lọ li ọjọ isimi, nwọn si wá si ọdọ Jehoiada alufa.

2. A. Ọba 11