26. Nwọn si kó awọn ere lati ile Baali jade, nwọn si sun wọn.
27. Nwọn si wo ere Baali lulẹ, nwọn si wo ile Baali lulẹ, nwọn si ṣe e ni ile igbẹ́ titi di oni yi.
28. Bayi ni Jehu pa Baali run kuro ni Israeli.
29. Ṣugbọn Jehu kò kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ti o mu Israeli ṣẹ̀, eyinì ni, awọn ẹgbọ̀rọ malu wura ti o wà ni Beteli, ati eyiti o wà ni Dani.
30. Oluwa si wi fun Jehu pe, Nitoriti iwọ ti ṣe rere ni ṣiṣe eyi ti o tọ́ li oju mi, ti o si ti ṣe si ile Ahabu gẹgẹ bi gbogbo eyiti o wà li ọkàn mi, awọn ọmọ rẹ iran kẹrin yio joko lori itẹ Israeli.
31. Ṣugbọn Jehu kò ṣe akiyesi lati ma fi gbogbo ọkàn rẹ̀ rin ninu ofin Oluwa Ọlọrun Israeli: nitoriti kò yà kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ti o mu Israeli ṣẹ̀.