23. Jehu si lọ, ati Jehonadabu ọmọ Rekabu sinu ile Baali, o si wi fun awọn olùsin Baali pe, Ẹ wá kiri, ki ẹ si wò ki ẹnikan ninu awọn iranṣẹ Oluwa ki o má si pẹlu nyin nihin, bikòṣe kìki awọn olùsin Baali.
24. Nigbati nwọn si wọle lati ru ẹbọ ati ọrẹ-sisun, Jehu yàn ọgọrin ọkunrin si ode, o si wipe, Bi ẹnikan ninu awọn ọkunrin ti mo mu wá fi le nyin lọwọ ba lọ, ẹniti o ba jẹ ki o lọ, ẹmi rẹ̀ yio lọ fun ẹmi tirẹ̀.
25. O si ṣe, bi a si ti pari ati ru ẹbọ sisun, ni Jehu wi fun awọn olùṣọ ati awọn olori-ogun pe, Wọle, ki ẹ si pa wọn; ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o jade. Nwọn si fi oju idà pa wọn; awọn olùṣọ ati awọn olori-ogun si gbé wọn sọ si ode, nwọn si wọ̀ inu odi ile Baali.
26. Nwọn si kó awọn ere lati ile Baali jade, nwọn si sun wọn.