2. A. Ọba 1:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni Moabu ṣọ̀tẹ si Israeli lẹhin ikú Ahabu.

2. Ahasiah si ṣubu lãrin fèrese ọlọnà kan ni iyara òke rẹ̀ ti o wà ni Samaria, o si ṣàisan: o si rán awọn onṣẹ o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ẹ bère lọwọ Baalsebubu, oriṣa Ekroni, bi emi o là ninu aisan yi.

3. Ṣugbọn angeli Oluwa wi fun Elijah, ara Tiṣbi pe, Dide, gòke lọ ipade awọn onṣẹ ọba Samaria, ki o si wi fun wọn pe, Kò ṣe pe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli, ni ẹnyin fi nlọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni?

2. A. Ọba 1