Ifi 9:6-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Li ọjọ wọnni li awọn enia yio si mã wá ikú, nwọn kì yio si ri i; nwọn o si fẹ lati kú, ikú yio si sá kuro lọdọ wọn.

7. Iré awọn ẽṣú na si dabi awọn ẹṣin ti a mura silẹ fun ogun; ati li ori wọn ni bi ẹnipe awọn ade ti o dabi wura wà, oju wọn si dabi oju enia;

8. Nwọn si ni irun bi irun obinrin, ehin wọn si dabi ti kiniun.

9. Nwọn si ni awo ìgbàiya, bi awo ìgbàiya irin; iró iyẹ́ wọn si dabi iró kẹkẹ́ ẹṣin pupọ̀ ti nsúré lọ si ogun.

10. Nwọn si ni ìru ati oró bi ti akẽkẽ, ati ni ìru wọn ni agbara wọn wà lati pa enia lara fun oṣù marun.

11. Nwọn ni angẹli ọgbun na bi ọba lori wọn, orukọ rẹ̀ li ede Heberu ni Abaddoni, ati li ède Griki orukọ rẹ̀ amã jẹ Apollioni.

12. Egbé kan kọja; kiyesi i, egbé meji mbọ̀ sibẹ lẹhin eyi.

13. Angẹli kẹfa si fun, mo si gbọ́ ohùn kan lati ibi iwo mẹrin pẹpẹ wura wá, ti mbẹ niwaju Ọlọrun,

14. Nwi fun angẹli kẹfa na ti o ni ipè na pe, Tú awọn angẹli mẹrin nì silẹ ti a dè lẹba odò nla Eufrate.

Ifi 9