16. Iye ogun awọn ẹlẹṣin si jẹ ãdọta ọkẹ́ lọna igba: mo si gbọ́ iye wọn.
17. Bayi ni mo si ri awọn ẹṣin na li ojuran, ati awọn ti o gùn wọn; nwọn ni awo ìgbaiya iná, ati ti jakinti, ati ti imí ọjọ: ori awọn ẹṣin na si dabi ori awọn kiniun; ati lati ẹnu wọn ni iná, ati ẹ̃fin, ati imí ọjọ ti njade.
18. Nipa iyọnu mẹta wọnyi li a ti pa idamẹta enia, nipa iná, ati nipa, ẹ̃fin, ati nipa imí ọjọ ti o nti ẹnu wọn jade.
19. Nitoripe agbara awọn ẹṣin na mbẹ li ẹnu wọn ati ni iru wọn: nitoripe ìru wọn dabi ejò, nwọn si ni ori, awọn wọnyi ni nwọn si fi npa-ni-lara.