1. ANGẸLI karun si fun, mo si ri irawọ kan bọ́ si ilẹ lati ọrun wá: a si fi iṣika iho ọgbun fun u.
2. O si ṣí iho ọgbun na; ẹ̃fin si ru jade lati inu iho na wá, bi ẹ̃fin ileru nla; õrùn ati oju sanma si ṣõkun nitori ẹ̃fin iho na.
3. Ẽṣú si jade ti inu ẹ̃fin na wá sori ilẹ: a si fi agbara fun wọn bi akẽkẽ ilẹ ti li agbara.
4. A si sọ fun wọn pe ki nwọn ki o máṣe pa koriko ilẹ lara, tabi ohun tutù kan, tabi igikigi kan; bikoṣe awọn enia ti kò ni èdidi Ọlọrun ni iwaju wọn.
5. A si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe pa wọn, ṣugbọn ki a dá wọn li oró li oṣù marun: oró wọn si dabi oró akẽkẽ, nigbati o ba ta enia.
6. Li ọjọ wọnni li awọn enia yio si mã wá ikú, nwọn kì yio si ri i; nwọn o si fẹ lati kú, ikú yio si sá kuro lọdọ wọn.