Ifi 8:12-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Angẹli kẹrin si fun, a si kọlu idamẹta õrùn, ati idamẹta oṣupa, ati idamẹta awọn irawọ, ki idamẹta wọn le ṣõkun, ki ọjọ maṣe mọlẹ fun idamẹta rẹ̀, ati oru bakanna.

13. Mo si wò, mo si gbọ́ idì kan ti nfò li ãrin ọrun, o nwi li ohùn rara pe, Egbé, egbé, egbé, fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye nitori ohùn ipè iyoku ti awọn angẹli mẹta ti mbọwá fun.

Ifi 8