10. Nwọn si kigbe li ohùn rara, wipe, Igbala ni ti Ọlọrun wa ti o joko lori itẹ́, ati ti Ọdọ-Agutan.
11. Gbogbo awọn angẹli si duro yi itẹ́ na ká, ati yi awọn àgba ati awọn ẹda alãye mẹrin na ká, nwọn wolẹ nwọn si dojubolẹ niwaju itẹ́ na nwọn si sìn Ọlọrun,
12. Wipe, Amin: Ibukún, ati ogo, ati ọgbọ́n, ati ọpẹ́, ati agbara, ati ipá fun Ọlọrun wa lai ati lailai. Amin.
13. Ọkan ninu awọn àgba na si dahùn, o bi mi pe, Tali awọn wọnyi ti a wọ̀ li aṣọ funfun nì? nibo ni nwọn si ti wá?