Ifi 6:6-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Mo si gbọ́ bi ẹnipe ohùn kan li arin awọn ẹda alãye mẹrẹrin nì ti nwipe, Oṣuwọn alikama kan fun owo idẹ kan, ati oṣuwọn ọkà barle mẹta fun owo idẹ kan; si kiyesi i, ki o má si ṣe pa oróro ati ọti-waini lara.

7. Nigbati o si ṣí èdidi kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye kẹrin nwipe, Wá wò o.

8. Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin rọndọnrọndọn kan: orukọ ẹniti o joko lori rẹ̀ ni Ikú, ati Ipò-okú si tọ̀ ọ lẹhin. A si fi agbara fun wọn lori idamẹrin aiye, lati fi idà, ati ebi, ati ikú, ati ẹranko ori ilẹ aiye pa.

9. Nigbati o si ṣí èdidi karun, mo ri labẹ pẹpẹ, ọkàn awọn ti a ti pa nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí ti nwọn dìmu:

10. Nwọn kigbe li ohùn rara, wipe, Yio ti pẹ to, Oluwa, Ẹni-Mimọ́ ati olõtọ, iwọ ki yio ṣe idajọ ki o si gbẹsan ẹ̀jẹ wa mọ́ lara awọn ti ngbé ori ilẹ aiye?

11. A si fi aṣọ funfun fun gbogbo wọn; a si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o simi di ìgba diẹ na, titi iye awọn iranṣẹ ẹlẹgbẹ ati arakunrin wọn ti a o pa bi wọn, yio fi pé.

12. Nigbati o si ṣí èdidi kẹfa mo si ri, si kiyesi i, ìṣẹlẹ nla kan ṣẹ̀; õrùn si dudu bi aṣọ-ọfọ onirun, oṣupa si dabi ẹ̀jẹ;

13. Awọn irawọ oju ọrun si ṣubu silẹ gẹgẹ bi igi ọpọtọ iti rẹ̀ àigbó eso rẹ̀ dànu, nigbati ẹfũfu nla ba mì i.

14. A si ká ọ̀run kuro bi iwe ti a ká; ati olukuluku oke ati erekuṣu li a si ṣí kuro ni ipò wọn.

15. Awọn ọba aiye ati awọn ọlọlá ati awọn olori ogun, ati awọn ọlọrọ̀ ati awọn alagbara, ati olukuluku ẹrú, ati olukuluku omnira, si fi ara wọn pamọ́ ninu ihò-ilẹ, ati ninu àpata ori òke:

16. Nwọn si nwi fun awọn òke ati awọn àpata na pe, Ẹ wólu wa, ki ẹ si fi wa pamọ́ kuro loju ẹniti o joko lori itẹ́, ati kuro ninu ibinu Ọdọ-Agutan na:

17. Nitori ọjọ nla ibinu wọn de; tani si le duro?

Ifi 6