Ifi 6:2-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin funfun kan: ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni ọrun kan; a si fi ade kan fun u: o si jade lọ lati iṣẹgun de iṣẹgun.

3. Nigbati o si ṣí èdidi keji, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye keji nwipe, Wá, wò o.

4. Ẹṣin miran ti o pupa si jade: a si fi agbara fun ẹniti o joko lori rẹ̀, lati gbà alafia kuro lori ilẹ aiye, ati pe ki nwọn ki o mã pa ara wọn: a si fi idà nla kan le e lọwọ.

5. Nigbati o si ṣí èdidi kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye kẹta nwipe, Wá, wò o. Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin dúdu kan; ẹniti o joko lori rẹ̀ ni oṣuwọn awẹ́ meji li ọwọ́ rẹ̀.

6. Mo si gbọ́ bi ẹnipe ohùn kan li arin awọn ẹda alãye mẹrẹrin nì ti nwipe, Oṣuwọn alikama kan fun owo idẹ kan, ati oṣuwọn ọkà barle mẹta fun owo idẹ kan; si kiyesi i, ki o má si ṣe pa oróro ati ọti-waini lara.

7. Nigbati o si ṣí èdidi kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye kẹrin nwipe, Wá wò o.

8. Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin rọndọnrọndọn kan: orukọ ẹniti o joko lori rẹ̀ ni Ikú, ati Ipò-okú si tọ̀ ọ lẹhin. A si fi agbara fun wọn lori idamẹrin aiye, lati fi idà, ati ebi, ati ikú, ati ẹranko ori ilẹ aiye pa.

9. Nigbati o si ṣí èdidi karun, mo ri labẹ pẹpẹ, ọkàn awọn ti a ti pa nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí ti nwọn dìmu:

10. Nwọn kigbe li ohùn rara, wipe, Yio ti pẹ to, Oluwa, Ẹni-Mimọ́ ati olõtọ, iwọ ki yio ṣe idajọ ki o si gbẹsan ẹ̀jẹ wa mọ́ lara awọn ti ngbé ori ilẹ aiye?

Ifi 6