Ifi 4:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LẸHIN nkan wọnyi emi wo, si kiyesi i, ilẹkun kan ṣí silẹ li ọrun: ohùn kini ti mo gbọ bi ohùn ipè ti mba mi sọ̀rọ, ti o wipe, Goke wa ìhin, emi o si fi ohun ti yio hù lẹhin-ọla hàn ọ.

2. Lojukanna mo si wà ninu Ẹmí: si kiyesi i, a tẹ́ itẹ́ kan li ọrun, ẹnikan si joko lori itẹ́ na.

3. Ẹniti o si joko na dabi okuta jaspi ati sardi ni wiwo: oṣumare si ta yi itẹ́ na ká, o dabi okuta smaragdu ni wiwo.

4. Yi itẹ́ na ká si ni itẹ́ mẹrinlelogun: ati lori awọn itẹ́ na mo ri awọn àgba mẹrinlelogun joko, ti a wọ̀ li aṣọ àlà; ade wura si wà li ori wọn.

5. Ati lati ibi itẹ́ na ni mànamána ati ãrá ati ohùn ti jade wá: fitila iná meje si ntàn nibẹ̀ niwaju itẹ́ na, ti iṣe Ẹmi meje ti Ọlọrun.

6. Ati niwaju itẹ́ na si ni okun bi digí, o dabi kristali: li arin itẹ́ na, ati yi itẹ́ na ká, li ẹda alãye mẹrin ti o kún fun oju niwaju ati lẹhin.

Ifi 4