Ifi 3:6-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ.

7. Ati si angẹli ijọ ni Filadelfia kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o jẹ mimọ́ ni wi, ẹniti iṣe olõtọ, ẹniti o ni kọkọrọ Dafidi, ẹniti o ṣí, ti kò si ẹniti yio tì; ẹniti o si tì, ti kò si ẹniti yio ṣí.

8. Emi mọ̀ iṣẹ rẹ: kiyesi i, mo gbé ilẹkun ti o sí kalẹ niwaju rẹ, ti kò si ẹniti o le tì ì: pe iwọ li agbara diẹ, iwọ si pa ọ̀rọ mi mọ́, iwọ kò si sẹ́ orukọ mi.

9. Kiyesi i, emi o mú awọn ti sinagogu Satani, awọn ti nwọn nwipe Ju li awọn, ti nwọn kì si iṣe bẹ̃, ṣugbọn ti nwọn nṣeke; kiyesi i, emi o mu ki nwọn wá wolẹ niwaju ẹsẹ rẹ, ki nwọn si mọ pe emi ti fẹ ọ.

10. Nitoriti iwọ ti pa ọ̀rọ sũru mi mọ́, emi pẹlu yio pa ọ mọ́ kuro ninu wakati idanwo ti mbọ̀wa de ba gbogbo aiye, lati dán awọn ti ngbe ori ilẹ aiye wo.

Ifi 3