11. Kiyesi i, emi mbọ̀ nisisiyi: di eyiti iwọ ni mu ṣinṣin, ki ẹnikẹni ki o máṣe gbà ade rẹ.
12. Ẹniti o ba ṣẹgun, on li emi o fi ṣe ọwọ̀n ninu tẹmpili Ọlọrun mi, on kì yio si jade kuro nibẹ mọ́: emi o si kọ orukọ Ọlọrun mi si i lara, ati orukọ ilu Ọlọrun mi, ti iṣe Jerusalemu titun, ti o nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun mi wá, ati orukọ titun ti emi tikarami.
13. Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ.
14. Ati si angẹli ijọ ni Laodikea kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti ijẹ Amin wi, ẹlẹri olododo ati olõtọ, olupilẹṣẹ ẹda Ọlọrun.