1. ATI si angẹli ijọ ni Sardi kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o ni Ẹmí meje Ọlọrun, ati irawọ meje nì wipe; Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati pe iwọ ni orukọ pe iwọ mbẹ lãye, ṣugbọn iwọ kú.
2. Mã ṣọra, ki o si fi ẹsẹ ohun ti o kù mulẹ, ti o ṣe tan lati kú: nitori emi kò ri iṣẹ rẹ ni pipé niwaju Ọlọrun.
3. Nitorina ranti bi iwọ ti gbà, ati bi iwọ ti gbọ́, ki o si pa a mọ, ki o si ronupiwada. Njẹ, bi iwọ kò ba ṣọra, emi o de si ọ bi olè, iwọ kì yio si mọ̀ wakati ti emi o de si ọ.