1. O si fi odò omi ìye kan han mi, ti o mọ́ bi kristali, ti nti ibi itẹ́ Ọlọrun ati ti Ọdọ-Agutan jade wá.
2. Li ãrin igboro rẹ̀, ati niha ikini keji odò na, ni igi iye gbé wà, ti ima so onirũru eso mejila, a si mã so eso rẹ̀ li oṣõṣù: ewé igi na si ni fún mimú awọn orilẹ-ède larada.
3. Ègún kì yio si si mọ́: itẹ́ Ọlọrun ati ti Ọdọ-Agutan ni yio si mã wà nibẹ̀; awọn iranṣẹ rẹ̀ yio si ma sìn i:
4. Nwọn o si mã ri oju rẹ̀; orukọ rẹ̀ yio si mã wà ni iwaju wọn.
5. Oru kì yio si si mọ́; nwọn kò si ni iwá imọlẹ fitila, tabi imọlẹ õrùn; nitoripe Oluwa Ọlọrun ni yio tan imọlẹ fun wọn: nwọn o si mã jọba lai ati lailai.
6. O si wi fun mi pe, ododo ati otitọ li ọ̀rọ wọnyi: Oluwa Ọlọrun ẹmi awọn woli li o si rán angẹli rẹ̀ lati fi ohun ti kò le ṣaiṣẹ kánkán hàn awọn iranṣẹ rẹ̀.
7. Kiyesi i, emi mbọ̀ kánkán: ibukún ni fun ẹniti npa ọ̀rọ isọtẹlẹ inu iwe yi mọ́.
8. Emi Johanu li ẹniti o gbọ́ ti o si ri nkan wọnyi. Nigbati mo si gbọ́ ti mo si ri, mo wolẹ lati foribalẹ niwaju ẹsẹ angẹli na, ti o fi nkan wọnyi hàn mi.
9. Nigbana li o wi fun mi pe, Wo o, máṣe bẹ̃: iranṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ li emi, ati ti awọn arakunrin rẹ woli, ati ti awọn ti npa ọ̀rọ inu iwe yi mọ́: foribalẹ fun Ọlọrun.
10. O si wi fun mi pe, Máṣe fi èdidi dí ọ̀rọ isọtẹlẹ ti inu iwe yi: nitori ìgba kù si dẹ̀dẹ̀.
11. Ẹniti iṣe alaiṣõtọ, ki o mã ṣe alaiṣõtọ nṣó: ati ẹniti iṣe ẹlẹgbin, ki o mã ṣe ẹlẹgbin nṣó: ati ẹniti iṣe olododo, ki o mã ṣe olododo nṣó: ati ẹniti iṣe mimọ́, ki o mã ṣe mimọ́ nṣó.
12. Kiyesi i, emi mbọ̀ kánkán; ère mi si mbẹ pẹlu mi, lati san an fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀ yio ti ri.
13. Emi ni Alfa ati Omega, ẹni iṣaju ati ẹni ikẹhin, ipilẹṣẹ̀ ati opin.