10. O si mu mi lọ ninu Ẹmí si òke nla kan ti o si ga, o si fi ilu nì hàn mi, Jerusalemu mimọ́, ti nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá,
11. Ti o ni ogo Ọlọrun: imọlẹ rẹ̀ si dabi okuta iyebiye gidigidi, ani bi okuta jasperi, o mọ́ bi kristali;
12. O si ni odi nla ati giga, o si ni ẹnubode mejila, ati ni awọn ẹnubode na angẹli mejila ati orukọ ti a kọ sara wọn ti iṣe orukọ awọn ẹ̀ya mejila ti awọn ọmọ Israeli:
13. Ni ìha ìla-õrùn ẹnubode mẹta; ni ìha ariwa ẹnubode mẹta; ni ìha gusù ẹnubode mẹta; ati ni ìha ìwọ-õrùn ẹnubode mẹta.
14. Odi ilu na si ni ipilẹ mejila, ati lori wọn orukọ awọn Aposteli mejila ti Ọdọ-Agutan.
15. Ẹniti o si mba mi sọ̀rọ ni ifefe wura kan fun iwọn lati fi wọ̀n ilu na ati awọn ẹnubode rẹ̀, ati odi rẹ̀.
16. Ilu na si lelẹ ni ibú mẹrin li ọgbọgba, gigùn rẹ̀ ati ibú rẹ̀ si dọgba: o si fi ifefe nì wọ̀n ilu na, o jẹ ẹgbata oṣuwọn furlongi: gigùn rẹ̀ ati ibú rẹ̀ ati gìga rẹ̀ si dọ́gba.
17. O si wọ̀n odi rẹ̀, o jẹ ogoje igbọnwọ le mẹrin, gẹgẹ bi oṣuwọn enia, eyini ni, ti angẹli na.
18. Ohun ti a sì fi mọ odi na ni jasperi: ilu na si jẹ kìki wura, o dabi digí ti o mọ́ kedere.