Ifi 21:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MO si ri ọrun titun kan ati aiye titun kan: nitoripe ọrun ti iṣaju ati aiye iṣaju ti kọja lọ; okun kò si si mọ́.

2. Mo si ri ilu mimọ́ nì, Jerusalemu titun nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá, ti a mura silẹ bi iyawo ti a ṣe lọṣọ́ fun ọkọ rẹ̀.

3. Mo si gbọ́ ohùn nla kan lati ori itẹ́ nì wá, nwipe, Kiyesi i, agọ́ Ọlọrun wà pẹlu awọn enia, on ó si mã ba wọn gbé, nwọn o si mã jẹ enia rẹ̀, ati Ọlọrun tikararẹ̀ yio wà pẹlu wọn, yio si mã jẹ Ọlọrun wọn.

4. Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn; kì yio si si ikú mọ́, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bẹ̃ni ki yio si irora mọ́: nitoripe ohun atijọ ti kọja lọ.

5. Ẹniti o joko lori itẹ́ nì si wipe, Kiyesi i, mo sọ ohun gbogbo di ọtún. O si wi fun mi pe, Kọwe rẹ̀: nitori ọ̀rọ wọnyi ododo ati otitọ ni nwọn.

6. O si wi fun mi pe, O pari. Emi ni Alfa ati Omega, ipilẹṣẹ ati opin. Emi ó si fi omi fun ẹniti ongbẹ ngbẹ lati orisun omi ìye lọfẹ̃.

7. Ẹniti o ba ṣẹgun ni yio jogún nkan wọnyi; emi o si mã jẹ Ọlọrun rẹ̀, on o si mã jẹ ọmọ mi.

8. Ṣugbọn awọn ojo, ati alaigbagbọ́, ati ẹni irira, ati apania, ati àgbèrè, ati oṣó, ati abọriṣa, ati awọn eke gbogbo, ni yio ní ipa tiwọn ninu adagun ti nfi iná ati sulfuru jò: eyi ti iṣe ikú keji.

9. Ọkan ninu awọn angẹli meje nì, ti nwọn ni ìgo meje nì, ti o kún fun iyọnu meje ikẹhin si wá, o si ba mi sọ̀rọ wipe, Wá nihin, emi o fi iyawo, aya Ọdọ-Agutan, hàn ọ.

10. O si mu mi lọ ninu Ẹmí si òke nla kan ti o si ga, o si fi ilu nì hàn mi, Jerusalemu mimọ́, ti nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá,

Ifi 21