7. Nigbati ẹgbẹrun ọdún na ba si pé, a o tú Satani silẹ kuro ninu tubu rẹ̀.
8. Yio si jade lọ lati mã tàn awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni igun mẹrẹrin aiye jẹ, Gogu ati Magogu, lati gbá wọn jọ si ogun: awọn ti iye wọn dabi iyanrìn okun.
9. Nwọn si gòke lọ la ibú aiye ja, nwọn si yi ibudo awọn enia mimọ́ ká ati ilu ayanfẹ na: iná si ti ọrun sọkalẹ wá, o si jo wọn run.