Ifi 20:7-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nigbati ẹgbẹrun ọdún na ba si pé, a o tú Satani silẹ kuro ninu tubu rẹ̀.

8. Yio si jade lọ lati mã tàn awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni igun mẹrẹrin aiye jẹ, Gogu ati Magogu, lati gbá wọn jọ si ogun: awọn ti iye wọn dabi iyanrìn okun.

9. Nwọn si gòke lọ la ibú aiye ja, nwọn si yi ibudo awọn enia mimọ́ ká ati ilu ayanfẹ na: iná si ti ọrun sọkalẹ wá, o si jo wọn run.

10. A si wọ́ Èṣu ti o tàn wọn jẹ lọ sinu adagun iná ati sulfuru, nibiti ẹranko ati woli eke nì gbé wà, a o si mã dá wọn loro t'ọsan-t'oru lai ati lailai.

11. Mo si ri itẹ́ funfun nla kan, ati ẹni ti o joko lori rẹ̀, niwaju ẹniti aiye ati ọrun fò lọ; a kò si ri ãye fun wọn mọ́.

12. Mo si ri awọn okú, ati ewe ati àgba, nwọn duro niwaju itẹ; a si ṣi awọn iwe silẹ; a si ṣí awọn iwe miran kan silẹ ti iṣe iwe ìye: a si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe na, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.

13. Okun si jọ awọn okú ti mbẹ ninu rẹ̀ lọwọ; ati ikú ati ipo-okú si jọ okú ti o wà ninu wọn lọwọ: a si ṣe idajọ wọn olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ wọn.

Ifi 20