Ifi 20:11-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Mo si ri itẹ́ funfun nla kan, ati ẹni ti o joko lori rẹ̀, niwaju ẹniti aiye ati ọrun fò lọ; a kò si ri ãye fun wọn mọ́.

12. Mo si ri awọn okú, ati ewe ati àgba, nwọn duro niwaju itẹ; a si ṣi awọn iwe silẹ; a si ṣí awọn iwe miran kan silẹ ti iṣe iwe ìye: a si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe na, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.

13. Okun si jọ awọn okú ti mbẹ ninu rẹ̀ lọwọ; ati ikú ati ipo-okú si jọ okú ti o wà ninu wọn lọwọ: a si ṣe idajọ wọn olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ wọn.

14. Ati ikú ati ipo-okú li a si sọ sinu adagun iná. Eyi ni ikú keji.

Ifi 20